Back to Top

 Skip navigation

Ẹ káàbọ sí èto Census 2006. Ní ọjọ àìkú, ní ọjọkẹtàlélógún osù kẹrin odún, èto ikaniyan nlá yí o wáyé ní orílẹ èdè Irelandi. Ní èto census yí, àwa yí o ka gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ìlu ní alẹ ojo naa. Àwa yí ó lo gbogbo èsì tí a bá gbà fún àkosílẹ ki a ba le se ètò sílẹ fún ọjọ iwájú.

Kí ni à npè ní census?

Bawo ni èyí se kàn mí?

Ijẹ ó jẹ dandan fún mi lati dahun fọọmu census yi?

Ijẹ idaniloju àsírí wà nípa èsì tí mo bá fisílẹ?

Kí ni yí o sẹlẹ lẹhin èyí?

Bí mo bá ní ìbéèrè nkọ?

Níbo ní èmi yí o ti ri ìrànlọwọ lati fí dáhùn fọọmu yí?

Kí ni à npè ní census?

Census tí o n wáyé ní ọdọọdún marun marun jẹ èto ikaniyan lati ka gbogbo ènìyàn àti gbogbo ìdílé tí ó wà nínú ìlu.
Èto census tí o nbọ yí o wáyé ní ọjọ àìkú, ní ọjọkẹtàlélógún osù kẹrin odún 2006. Gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ìlu ní ọjọ naa ni ó jẹ dandan lati kà sí inu fọọmu census.
Ibikíbi tí o bá wà nínu ìlu - kì baa jẹ wípé o wà ní ilé ni orílẹ èdè Irelandi, tàbí o wà ní ọdọ ẹbí tàbí ọrẹ, tàbí o wà nínú ilé ìwòsàn, tàbí bẹẹ bẹẹ lọ, ó jẹ dandan lati kà ọ.

Bawo ni èyí se kàn mí?

Gbogbo ìdílé nínú ìlu ní a yí o fún ní fọọmu census yí. Nígbàtí ó bá di ọjọ census naa, èyí tí ó jẹ ọjọ àìkú, ní ọjọkẹtàlélógún osù kẹrin odún 2006, olórí ìdílé tàbí àgbàlagbà tí ó bá wà ní ilé ní alẹ ọjọ naa ni lati dahun fọọmu census yi.

Ijẹ ó jẹ dandan fún mi lati dahun fọọmu census yi?

Bẹẹni. Nítóríwípé gbogbo èsì tí a bá gbà ní census yí, yí o wúlò pàtàkì fún síse ètò ìdàgbàsókè fún ọjọ iwájú fún gbogbo wa pátápátá. Gẹgẹ bí àkọsilẹ òfin, o ní lati dáhùn fọọmu census yi.

Ijẹ idaniloju àsírí wà nípa èsì tí mo bá fisílẹ?

Dájúdájú. Akì yí ó sọ gbogbo ohunkóhun tí o bà fisílẹ ninú fọọmu rẹ fún ẹnìkankan. Eyí jẹ àkosilẹ òfin!

Kí ni yí o sẹlẹ lẹhin èyí?

Gbogbo agbègbè tí ó wà ní ìlu Irelandi, kà kún fí agbègbè rẹ ni ó ní awọn akànìyàn lorisirisi. Wọn jẹ awọn ẹni tí olórí ilé isẹ akànìyàn, èyì tí a pè ni Central Statistics Office gbà sí isẹ lati se isẹ census yi.
Akànìyàn agbègbè rẹ yí o wá sí ọdọ rẹ lati fun ọ ní fọọmu census àlàfo. Jọwọ tọju rẹ daa daa kí o sí dáhùn rẹ dédé ní alẹ ọjọ census naa. Akànìyàn agbègbè rẹ yí o pè ọ láìpẹ lẹhìn ọjọ census naa lati gba fọọmu tí o dáhùn.

Bí mo bá ní ìbéèrè nkọ?

Akànìyàn agbègbè rẹ tí se tán lati ran ọ lọwọ. Ó sí tún se tán lati dáhùn gbogbo ìbéèrè tí o bá ní nípa èto census yí tàbí nípa dídáhùn fọọmu census yí.
fọọmu census yí tún wà ní àwọn èdè mọkànlá míràn. Awọn ede yí ní ede arabia, ede shainisi, ede lituania, ede polishi, ede pọrtugí, ede romania, ede rọshia àti ede spanishi.

Báàyíbí, dahun fọọmu census rẹ ni ọjọ abameta ní ọjọkẹtàlélógún osù kẹrin odún 2006 kí o ba lè kópa nínú ohun pàtàkí tí ó and be part of the bigger picture.

Níbo ní èmi yí o ti ri ìrànlọwọ lati fí dáhùn fọọmu yí?

1. Akànìyàn agbègbè rẹ lè ràn ẹ lọwọ tàbí
2. o lè bèrè fún ìrànlọwọ lati ọwọ awọn ọrẹ tàbí ẹbí tàbí
3. tí o bá n'kọ ede gẹẹsi, o lè bèrè lọwọ olùkọ ede gẹẹsì rẹ fún ìrànlọwọ lati dáhùn fọọmu yí.

›  Àlàyé nípa Census 2006 (PDF 376KB)